Thursday, June 14, 2018

Ede Yoruba ati Oloogbe Adebayo Faleti


Oloogbe Adebayo Faleti je gbajumo osere ati onkotan lede Yoruba. 

Faleti, ti a bi lojo kerindinlogbon, osu kejila, odun 1921, je alakitiyan eniyan ti kii fi idagbasoke awujo Yoruba sere rara; yato si wi pe o je okan lara awon asaaju ninu ise ikaroyin ede Yoruba lori ero amohunmaworan lorilede Naijiria.
Bi o tile je pe awon ise takuntakun ti Adebayo Faleti gbe se lori igbende ati idagbasoke ere ori itage lori ero mohunmaworan ko see foju fo, amo ohun to je mi logun nihin ni ijinle ogbon atinuda ti Adebayo Faleti maa n lo lati fi se agbekale ewi re.

Okan lara ewi Oloogbe Adebayo Faleti ti mo feran ju ni “Ojo Ilayefun”; ewi ti Oloogbe Faleti ko lati fi maa ran wa leti pe o ye ki ore rere maa bo asiri ore re nibi gbogbo ati nigba gbogbo.

Ojo Ilayefun

Oniruuru ore la n ni:
Ore ire, ore ika;
Oto lore dabe-n-yanko,
Oto lore onibaje eniyan.
Kii se poree tooto ko si laye
Ibi ti won wa la o mo.
Sugbon won m be laarin kookan
Bi olomosikata ti wa laarin agbado
Nigba kan, igba kan
Niluu kan ti won n pe l’Asunnara,
Awon meji kan m be nibe, won n sore.
Ekini n je Sangodokun,
Ekeji si n je Laala;
Sangodokun ti niyawo ona,
Laala sese m b’Olodumare ni
Igba ti yo bu se gada, ti yob u se gede
Ni Sangodokun ba ko lugbona ode
Sangodokun dalaganna eniyan
O deni ti n sinwin kagbo ile kiri.
Bee ni won ko je ki ana re o gbo,
Ko ma waa dabi laifi leyin ola.
Ko ma dohun tii doju tini.
Ni won ba tete ro sekeseke meji
Won ko o sese Sangodokun,
Nitori bo ba n se were,
Ko ma dohun tipa ko nii le ka mo.
Won ko sekeseke sese tan
Won tun n fi patie soko fun un.
Bee Iyawo ku si dedede,
Iyawo re sese to o gbe ni,
Ki jannajanna to o gbara.
Laala ore re se kisa nibe
Igba to ya gbogbo re ro pese
Aisan-an were naa san fun Sangodokun.
Gbogbo ara ile re wa n yo sese
Pe were o si mo ninu iran awon.
Igba talaafia ti de fun Sangodokun,
To n sohun to ba ti gbogbo aye mu
Won ni ko gbewu wok o wa rele ana e.
(Se won so fun won po ti rebi ni).
Ni Sangodokun ba gbewu wo
Ni Laala ba mura, o gba tore e gerere.
Igba ti won dele ana re nko?
Gbogbo eniyan n yo fere,
Inu won dun pe won tun roko ape awon_
 Erin gbereke alatona, onigbowo pelu
Erin gbenu afesona Sangodokun.
Se won ko mohun to ti sele
Won de lati eyin-odi ni
Won ba yara madie opipi
Won yara lo madie osoro,
Won ti yara tami ape.
Won sare wonlubo kale gerere,
Won gbe e sinu igba niyara okankan
Ko jinna sibi won teni si fun Sangodokun,
Toun ati Laala feyin ti,
Ti won rogboku bi oba kotonkan.
Omi oka sese n fe ho ni ile idana
Baba omo, iya ati ara odede
Ni won n ro kukukeke
Ki won le tete gbounje falejo to bodale
Awon meji pere lo wa ku lodede
Laala pelu Sangodokun ni.
Igba o ya, Laala loun o to leekule,
O ba won nibi ina dida, o yanu.
Igba ti Laala yoo fi to tan, omi ho lori ina.
Iyayawo ku fiiri wole lati buyefun
Igba to wole ko ri Dokun
O woyara okankan ti won gbelubo si
Ibe niya iyawo ti ba Sangodokun
Ti n jelubo ekuku bi agutan,
Ti n lanu bi ewure jewe ata.
Iyefun to tip o nile kitikiti
Eyi toko iyawo la ku, ko kunwo!   
Iya iyawo kandi, ko mohun to le se;
O peyin da, o fe lo so fawon teekule
Loun Laala ba kora peki ni gbangba.
O ni, “Jowo, ore oko iyawo,
O o wa wohun toree re n se:
Elubo ta a bar o lamala
Loko iyawo ti fere je tan niyara”
Ologbon ni Laala, oloye ni,
O ti mo paaganna lo tun ko lore oun.
Ko woke to fi mudaahun wa,
O ni, “Abi awa le n dana fun?
Bi e ba wi ni, a ba ti je ki e dana
Nitori oni l’Ojo Ilayefun nile wa.
A ko gbodo je amala rara,
Bi a ba ti layefun ka mumi sii ni.”
Ni Laala ba bo sibi ti Dokun wa,
O bere si idi elubo, oun paapaa n layefun.
Niya iyawo ba n sipe pe ki won dakun,
Oun o tete mo ponii l’Ojo Ilayefun nle won.
Atiyawo ona, ati baba, atara ile,
Ni won jade wa woun ti n sele loode won.
Won ba Laala, won ba Sangodokun
(Won ti jelubo ekuku tan, igba e lo ku)
Won n fenu lagba bi olorikunkun eran.
Niya iyawo ba wa kejo kale, lo salaye
Pe lonii l’Ojo Ilayefun nile won
Ni gbogbo eniyan ba n se “Haa! A o mo!
E ma biinu, e fori ji wa, e dakun.”
Ni won ba n sure bomi mimu fun won.
Laala jelubo tan, o mumi, ikun wu banku
Lai-je-were, lai-tile-jasinwin
Sebi nitori kasiiri ore o le bo nile ana ni.
Asiri si bo titi won fi kuro nibe:
Awon ana sebi odun nla l’Ojo Ilayefun.
Awon mejeeji jelubo ekuku tan
Won ba mura o dadugbo won.
Won dele ni Laala wa kejo kale lo royin.
Ni won ba n dupe, won n sadua fun un
Funtiju to fi ba Sango layefun.
Won ba wa tun nawo gan Sangodokun
Won de e ni sekeseke lese.
Won poloogun nla to le rerun naa wo
Ko ba won le arun naa lo patapata.
  

Wednesday, June 13, 2018

Ogbufo Oro-Ise



Gege bi mo ti maa n so fun awon akekoo mi wi pe ede ti eniyan ba mo doju ami ni yoo se amulo lati fi to oju-ona ede ajeji ti oluwa re sese fe ni imo nipa re. Idi abajo re e ti mo fi mu un ni pataki lati se ogbufo die lara awon oro-ise ti a maa n lo ninu girama ede Yoruba si ede Geesi ati ede Faranse fun ekunrere imo awon akekoo.
Itowo ladun obe, mo pinnu lati tubo se eku loju eegun lori ogbufo oro-ise iyen lojo iwaju. 

YORÙBÁ
ENGLISH
FRENCH
Mu
Drink
Boire
Sáré
Run
Courir
Sèdá
Create
Créer
Parí
Finish
Finir
Drive
Conduire
Mo
Know
Connaître
Rán
Sew
Coudre
Cover
Couvrir
Gbàgbó
Believe
Croire
Say
Dire
Ko
Write
Écrire
Rán
Send
Envoyer
Se
Do
Faire
Dance
Dancer
Ko
Sing
Chanter
Dúró
Wait
Attendre
Have
Avoir
Buy
Acheter
Jókòó
Sit
Asseoir

Sunday, June 10, 2018

Orisa Sango



Yoruba maa n pa a lowe pe “eni ti Sango toju e wole, kii bawon pe e loba koso”
Sango je okan pataki ninu awon orisa nile Yoruba. Eyi losi fa a ti a fi maa n ri awon olusin Sango kaakiri ile kaaro-o-jiire. Sango ni a n pe ni ina-loju-ina-lenu (Afina fohun bi o ba soro), olukoso oko Oya.
Bi gbogbo orisa nile Yoruba se ni ojubo tiwon naa ni Sango ni ojubo tire. A si le ba asa ti a n pe ni Sango-Pipe ni awon ajodun ibile Sango, nibi oro Sango (eyi ni ibi ti awon adosu Sango ti se oro lati yo edun tabi oko ti Sango fi pa eniyan ladugbo kan), ati nibi eto isinku adosu Sango kan. Ona Mogba ni a n pe bale fun awon adosu Sango ni adugbo kan nitori pe orisirisi adugbo ni a le ba pade lawujo Yoruba.

Ti a ba n soro nipa Sango Pipe gege bi asa, oriki Sango ni eyi maa n ko sodi. Awon adosu Sango (yala lokunrin tabi lobinrin) lo maa n pe Sango bi o tile je pe awon obinrin lo sabaa maa n pe e, sibe ko yo awon okunrin naa sile. Ilana lile ati gbigbe ni won maa n lo lati fi pe Sango.
Apeere:-
Ayanrin ina
Olukoso Oko Oya
Ajala Iji, Ewelere, Ajija ote
Aara bowo ija lala
Ina gori ile feju
Iku tii pani tenikan o le mu
Sango, ma bami ja
No lowo ebo nile
Olubanbi, Ewelere mo sipe o
Ija a re gan-an oran
 Iku tii pani t’enikan kii ke
Afose yoni loju
Afedun yofun
Afeefin se ni pele
Afina fohun bi o ba soro.

Friday, June 8, 2018

Igbeyin Lalayo N Ta (Ori Keji)


Ori Keji:- OGUN OMODE KII SERE KAGUN ODUN
Obisesan bere ile-eko giga Moda ti o wa ni itosi won. O bere ile-iwe naa, o si ri iriri lorisirisi sugbon ni ojo kan, awon oluko le awon akekoo ti o je owo ile-iwe pada sile lati lo gba owo won wa. Kaka ki Obisesan ati awon ore re kori si ile obi won, odo-eja ni won gba lo.

Obisesan, Alonge, Oludele, Sangodiran ati Ijaodola bere si ni fi iwo ati ekolo de panpe fun awon eja ninu odo sugbon won ko ri eja pa lojo naa.

Lojiji ni ejo-ere nla kan jade lati inu igbo ti o si lo mo Alonge, die lo ku ki o gbe Alonge mi_ opelope ode ti o fi ibon re pa ejo-ere naa ti o si fun Alonge ni ado-ero ki ara re le bale leyin ti ejo ti fere gba emi lenu re.

Wednesday, June 6, 2018

Igbeyin Lalayo N Ta (Ori Kin-in-ni)


Ori Kin-in-ni:- IKU LO N POJU ARUN MO
Obisesan padanu baba re leyin ti baba re ti wa ni idubule aisan fun odun meta. Ni ile ti yoo mo ojo ti iku pa baba Obisesan, oun funra re ti rii loju ala pe awon kan n gbe saare-oku eni mimo.

Obisesan (aremu tabi "Dawodu") lo wa nibe nigba ti baba so oro ikeyin ki o to gba orun lo.

Obisesan, awon ebi, awon ara, ati awon iyawo baba re se iku baba re (eni-ire to ku iku aitojo) eto isinku naa, won si gboriyin.

Sunday, June 3, 2018

Olomoge

Olómoge tí n se fújà
Tétí kí o gbo ohun tí mo fé so fún o
Òpò ló ti soge bóge lo
Òpò lako ti lò mógbà
Ti wón wá gbó sása bí i aso
Ó dàgbèrè ìlú-mò-ón ká
Ti dúdú, ti pupa lò n bóra fun
Gbogbo ako ló mó ní pópó
Bí wón bá so e dako ajá tán
Tó o wá dàgbébò adìe
Ta ló fé gbé o sílé bí aya
Bó o bá bùrìn bùrìn
Bó o róko gbé o sílé
Ó pé, ó yá
Oko á bólómo lo
Olóbó kì í bímo
Àgbàtó ni wón fi n somo
Òwò tí kò pé
Òun lòwò àgbèrè
Ikú òjijì ló n bá tage
Éèdì, àtàtòsí ègbe
Lèrè eni n sòwò àgbèrè

(eni tó ewì yìí ni: Yèkínì Olátáyò.

Igbeyin Lalayo N Ta (Olusesan Ajewole)


Onkotan:- Agba onkowe ni Oloye Olusesan Ajewole ninu ede Yoruba ati Geesi. A bi i ni odun 1945 ni ilu Efon-Alaaye ni ipinle Ekiti. O lo si ile-eko Moda (Modern School).
Bakan naa ni o kekoo gboye ni ile-eko Olukoni onipo keji. O gboye ijinle ninu imo Gbigbegilerw ni ile-eko giga Gbogbonise (Polytechnic) ti ilu Ibadan. Lara awon iwe ti o ti ko ni; Pikin-o-gbodo-gbin; Kile to Posika; The Big Catch ati bee lo.

Gbolohun Iperi (synopsis):- Laaaro kutukutu ojo aye Obisesan ni o ti di omo alainibaba, eru eni meji di ti enikan. Ninu ilakaka re lati deniyan pataki, o lo si ile-eko. O kawe tan, ko rise; o ko sowo awon gbomogbomo; o se ise alagbaro; o tun kose-owo. Bawo lo se we okun aye ja? Ki ni oju awon omo alainibaba tabi omo orukan n ri lawujo wa? Se gbogbo won lo n didakuda laye? Ki ni ipa ti iforiti n ko ninu aye eda? Idahun si awon ibeere wonyi wa ninu itan oloyinmomo yii... IGBEYIN LALAYO N TA.

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday