Sunday, June 3, 2018

Igbeyin Lalayo N Ta (Olusesan Ajewole)


Onkotan:- Agba onkowe ni Oloye Olusesan Ajewole ninu ede Yoruba ati Geesi. A bi i ni odun 1945 ni ilu Efon-Alaaye ni ipinle Ekiti. O lo si ile-eko Moda (Modern School).
Bakan naa ni o kekoo gboye ni ile-eko Olukoni onipo keji. O gboye ijinle ninu imo Gbigbegilerw ni ile-eko giga Gbogbonise (Polytechnic) ti ilu Ibadan. Lara awon iwe ti o ti ko ni; Pikin-o-gbodo-gbin; Kile to Posika; The Big Catch ati bee lo.

Gbolohun Iperi (synopsis):- Laaaro kutukutu ojo aye Obisesan ni o ti di omo alainibaba, eru eni meji di ti enikan. Ninu ilakaka re lati deniyan pataki, o lo si ile-eko. O kawe tan, ko rise; o ko sowo awon gbomogbomo; o se ise alagbaro; o tun kose-owo. Bawo lo se we okun aye ja? Ki ni oju awon omo alainibaba tabi omo orukan n ri lawujo wa? Se gbogbo won lo n didakuda laye? Ki ni ipa ti iforiti n ko ninu aye eda? Idahun si awon ibeere wonyi wa ninu itan oloyinmomo yii... IGBEYIN LALAYO N TA.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday