Friday, January 25, 2019

Ila Kiko Nile Yoruba (Yoruba Tribal Marks)



“Aluwala olonginin, ogbon ati keran je ni”; asa ila kiko ni gbolohun yii n fi ogbon bawi nitori pe ogboogbon ni ila kiko gba di asa nile kaaro-o-jiire.

Orisirisi itan agboso ni o ro mo asa yii. Itan kan toka si I pea won eru nikan ni won n ko ila nile Yoruba laye atijo (awon eru oba). Amo sababi kan mu ki won fi ibinu ko ila fun eru kan gege bi ijiya fun ese re laimo pe ila ti a ko fun eru yii yoo mu un tubo rewa si i ni. Nigba ti ila naa ti so eru ohun di arewa ni oba naa ba pinnu pe oun  naa yoo ko irufe ila bee. Nigba ti oloola bere si ni ko ila fun oba, tiroratirora ni debi pe oba ohun ko le mara duro ko ila naa tan. Iru iwa yii lo bi owe Yoruba to so pe “Tita riro laa kola, amo ti o ba jinna tan nii doge”. Itan yii fi han pe bi ila kiko se di ohun amusoge lawujo awon Oduduwa niyen.

A si tun ri itan miiran to fi han pe nigba laelae, nile Yoruba, ogun ati ikonileru gbile bi owara-ojo; eyi si n ko orisirisi ipinya airotele ba awon ebi (bi ogun ati ikonileru se n ya oko ati iyawo, bee ni o n ya awon obi kuro lodo awon omo won). Eyi lo mu ki awon ebi kookan gunle orisi ila kiko gege bi ogbon idanimo ntori igbagbo Yoruba wi pe lojo eni ti o ku ati eni to sonu yoo pade ara won.

Nje ki wa ni awon idi ti Yoruba fi n ko ila? (i) fun idanimo (ii) fun oge sise (iii) fun igbelaruge asa Yoruba.

Orisirisi ni ila kiko ni ile Yoruba. Bee ni o si yato si ara won lati agbegbe kan si ekeji. Awon ila bi pele, abaja, baamu, abaja pelu baamu, gonbo, gonbo pelu baamu, keke, ture, ati bee lo ni won n ko nile Yoruba sugbon eya Yooba kookan ni o ni orisi ila tire.

Si tun se Pataki fun wa lati ranti pe eniyan ti o yan ise ila kiko laayo ni a n pe ni Oloola. Iru ise bayii si le je ajogunba tabi kiko lati inu ebi to yan an laayo.
Nje O Ti Ka:

Iro Ohun ati Ami Ohun (Yoruba Tonal Sounds and Signs)


Ifa ati Eko Imo Ijinle Saikoloji


No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday