Friday, January 25, 2019

Itoju Ara Ati Ayika (Cleanliness)



Lati le dena arun ati aisan ni imototo fi se Pataki. Ona ti a si n gba ni imototo ni ki a se itoju ara ati ayika.
1.       Iwe wiwe wa lara ipa ti eniyan maa n ko lati toju ara. Ki a fi ose ati kan-in-kan-in ti o dara pelu girisi (ipara) fun ara ni ewa ti o ye.
2.       Eyin fifo se Pataki fun enikeni to ba few a ni imototo. Eyi se Pataki loorekoore nigba ti eniyan ba ji lowuro ati nigba ti eniyan ba fe lo sun. Burosi tabi pako irunyin ni a fi n foe yin mo.
3.       Itoju irun-ori ti wa lati igba laelae titi di oni; tokunrin tobinrin lo si maa n toju irun. Awon obinrin gbodo se irun ni kiko tabi ni didi nigba ti awon obinrin maa n ge irun won . O tun je kannpa lati maa fi omi ati ose fo irun wa.
4.       Itoju eekanna owo ati eekanna ese nipa ki a maa ge won, ki a si maa fo won lati dekun idoti to fe tabi to le farapamo sisun awon eekanna wa.
5.       Itoju aso o gbeyin ninu akitiyan lati dena arun to le kolu ara nipa ki eniyan ma wa ni imototo. Nse ni a gbodo maa fo awon aso wa pelu ose ati omi to mo.
6.       Itoju ayika (yala_ ile-igbe, ile-eko, ile-ise, tabi oja) se Pataki bakan naa. Eyi ni ko ni je ki eniyan je oye adara-lode-ma-dara-nile tabi adara-nile-ma-dara-lode. Lojoojumo ni o ye ki a maa fi igbale gba gbogbo ayika wa. A sit un gbodo maa gbon gbogbo panti ati jankariwo to so mo ile. A gbodo sa gbogbo agolo, igo-afoku, ewe ati ora tabi ohunkohun to le ko ijamba ba eniyan. A gbodo maa gba, ki a si tun maa fo oju gota ati oju-ona agbara, ki a si tun di awon ibi ti salanga ba ti fo lati dena arun ti eniyan le ko lati ipase oorun buruku. A gbodo maa se itoju ti o ye fun awon ile-iwe, ile-igbonse ati ati ayika idana. A gbodo maa ro awon oko ayika, ki a sit un ko gbogbo ohun ti ejo, efon, akeekee ati eku le farapamo si se eniyan ni ijamba jina si ayika ileegbe.
Ise imototo ko yo enikeni sile; ijoba, elegbejegbe,odo adugbo nitori pe agbajowo ni a fi n soya.
Nje O Ranti :

1. Orisirisi Oro-Ise 2

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday