Tuesday, May 29, 2018

Oju-Owo, Ere Ati Okuta

Ninu eko adalori kara-kata ni a ti saba maa n ba awon oro wonyi pade. O tumo si wi pe inu opon-ifa owo sise ni a ti i lo won. 

Oju-owo: Eyi ni owo ti onisowo (ti a tun mo si ontaja) ko jo lati fi bere owo ni sise; awon oloyinbo maa n pe e ni Principal.

 Gbogbo oro ninu ede yoruba lo ni owe tabi asayan oro ti a maa n lo pelu e. Eyi lo fa a ti eniyan le fi toka si ohun to niyi gege bi ohun to ka oju-owo. (Apeere: ebun naa ka oju-owo).

 Ere: Yoruba maa n pa a lowe pe "ere ni obinrin n je labo oja". Kin ni ere? Ere ni owo ti ontaja pa kun oju-owo leyin ti o ta oja re tan; a maa n pe ere ni "profit" tabi "gain" ni ede Geesi.

Eyi je idi pataki ti awon eniyan fi maa n sowo_ won a se owo ki won le ri apakun owo, won a se owo ki won le ta atajere.

Ojuta: A le pe okuta ni aseeeri ti o waye ninu owo sise tabi oja tita. Awon eniyan tun maa n pe e ni airere je. Ki Eledumare, Oba Adarihurun, ma se je ki a ba okuta pade nile aye; ase o. Kin wa ni a le pe okuta ni ede Geesi? Oun ni a n pe ni "loss". Okuta o dara.

Eyi lo fa a ti onisowo fi maa n ja fitafita lati ri oju-owo ko jo bi ogbon ati je ere ba doju de.

 Bi eniyan ba se owo tabi ta oja laarin ojo kan, o rorun fun iru eni bee lati mo boya oun ti je ere tabi oun ti ba okuta pade.

Sugbon ninu isowo ti yoo gba ontaja ni opolopo osu tabi opolopo odun, o se pataki fun ontaja lati ni iwe akosile owo to gun rege_ iyen "proper bookkeeping" ni ede Geesi lati le je ki o rorun fun ontaja nigba ti o ba n se isiro oja re.

Saturday, May 26, 2018

Otunla, Ijeta Ati Idunta

Ki a to gunle iyato to wa laarin otunla, ijeta ati idunta_ o se pataki lati mo pe omo iya kan ni won on se nitori pe gbogbo won n toka akoko tabi igba ti ohun kan tabi isele kan waye.

Iyato ibe fara han lati ibi wi pe ona ti won gbe n toka akoko yato si ara won.

Otunla: Eyi ni a le pe ni ojo keta si ojo ti a wa yii. Awon oloyinbo maa n pe e ni (in three days time). Ninu akaba ojo tabi akoko, ola ni a maa kan ki a to kan otunla.
Apeere: Mo pinnu lati ba yin lo si ibe ni otunla.

Ijeta: Eyi ni a le pe ni ojo keta seyin ojo ti a wa yii. Oun ni a maa n pe ni (three days ago) ni ede geesi. Ana ni o tele ijeta, leyin ana ni o kan oni tabi ojo-oni.
Apeere: Nje awon omo naa pade ni ijeta?

Idunta: Eyi ni a le pe ni odun keta seyin odun ti a wa yii. (Three years ago) ni awon oloyinbo n pe e. Esi tabi odun-esi ni o tele idunta, leyin esi ni o kan odun ti a wa yii.
Apeere: Awa se idunta bee ni a se odun esi bakan naa ni a o se odun yii layo ati alaafia.

Sunday, May 13, 2018

Awe-Gbolohun Afibo Ati Awe-Gbolohun Asapejuwe


Awe-gbolohun afibo ati Awe-gbolohun asapejuwe

A ti mo wi pe ni abo fun odindi gbolohun yala o le da duro tabi ko le da duro.

Bi a ba wo ibasepo to wa laarin awe-gbolohun afibo ati awe-gbolohun asapejuwe, a le fowo soya pe awe-gbolohun asapejuwe ni awe-gbolohun afibo ti o n sise eyan ninu gbolohun ede Yoruba.

Apeere:
Ajiboye gba pe ounje gidi ni iyan (awe-gbolohun afibo)
Ile ti Ade ko ti wo lana (awe-gbolohun asapejuwe).

Friday, May 4, 2018

Yoruba Objective 3


Yoruba Q and A 3


  1. "Ayo ti korin" 'ti' je iba-isele

  2. A. baraku
    B. aisetan
    C. asetan

  3. "Mo ra iwe fun Gbemi" 'mo' je oro-aropo-oruko

  4. A. eni keji eyo
    B. eni keji opo
    C. eni kinni eyo

  5. Isori oro ti o maa n saaju apola oruko ninu apola aponle ni

  6. A. oro-atokun
    B. oro-ise
    C. oro-apejuwe

  7. A word is enough for the wise

  8. A. oro kan to fun eni ti o ti gbon
    B. abo oro laa so feni to ba gbon
    C. abo oro laa so fomoluwabi

  9. The man is very generous

  10. A. okunrin naa kanra gan-an
    B. okunrin naa lawo gan-an
    C. okunrin naa je alafe eniyan

  11. "Ewo ni alo?" 

  12. A. ma se fowuro sere
    B. ojo re a dale
    C. opa teere kanle o kanrun

  13. "O lowo lowo bii sekere" je ____

  14. A. afiwe
    B. awitunwi
    C. iforogbe-oro

  15. Ile meloo ni opon ayo maa n ni?

  16. A. merinlelogun
    B. mefa
    C. mejila

  17. Orisa wo ni a n ki ni "Olukoso"

  18. A. Sango
    B. Oya
    C. Obatala

  19. Olori awo oro ni a n pe ni

  20. A. alapin-in-ni
    B. erelu
    C. ajana

Yoruba Objective 2

Yoruba Q and A 2


  1. "Ile ti gbe" tumo si pe

  2. A. oju ti da
    B. wahala po
    C. nnkan ti tan

  3. "E jowo e fori ji wa" je apeere

  4. A. iwure
    B. ofo
    C. ebe

  5. "Esentaye" je mo asa

  6. A. omo bibi
    B. iranranilowo
    C. ikoseyege

  7. Idile wo lo n so omo ni Opadiji

  8. A. eleegun
    B. onisango
    C. olorisaoko

  9. Irinse fun aso hihun ni

  10. A. awon
    B. owu
    C. keke

  11. Ki ni aso Ogun 

  12. A. eweeran
    B. goodogi
    C. mariwo

  13. Ohun elo ogun jija ni ____

  14. A. ibon
    B. eya
    C. emu

  15. Ewo lo pari pelu ami ohun aarin?

  16. A. iyan
    B. asa
    C. ofin

  17. Oro used a ni ____

  18. A. ara
    B. penpe
    C. dugbe

  19. Ninu "Mo lo si ibi igbeyawo" 'si' je _____

  20. A. oro-apejuwe
    B. oro-oruko
    C. oro-atokun

Yoruba Objective 1

Yoruba Q and A 1


  1. Leta aigbagbefe nikan lo Maya n ni ______

  2. A. adiresi
    B. oruko akoleta
    C. ori-oro

  3. Abuda wo lo ya faweli aranmupe soto si faweli airanmupe?

  4. A. giga ahon
    B. ipo ti ete wa
    C. ipo ti afase wa

  5. Ninu "Olu ba egbon re ja", 'ba....ja' je oro-ise

  6. A. elela
    B. asebeere
    C. alapepada

  7. Olu broke Sola's heart

  8. A. Olu fo okan Sola
    B. Olu da inu Sola ru
    C. Olu ba Sola ninu je

  9. The student was commended for his brilliance

  10. A. akekoo naa gboriyin fun ijafafa re
    B. akekoo naa gboriyin fun ori pipe re
    C. akekoo naa gboriyin fun aigbagbera re

  11. "Ifeto-somo-bibi" je ori-oro fun aroko

  12. A. asotan
    B. asapejuwe
    C. ajemo-isipaya

  13. [r] je iro _____

  14. A. aferigipe
    B. afajape
    C. afejifetepe

  15. Iparoje waye ninu ___?

  16. A. kaabo
    B. osoose
    C. rugi

  17. Irufe awe-gbolohun asaponle to wa ninu "O jeun nigba ti ebi n pa a" ni

  18. A. alasiko
    B. onibi
    C. alafiwe

  19. The road may be slippery

  20. A. ona naa a ti maa yo
    B. ona naa n yo
    C. ona naa le maa yo

Yoruba Objective

Yoruba Q and A


  1. Aikunyun ni ______

  2. A. [l]
    B. [r]
    C. [f]

  3. Ewo ni faweli aarin

  4. A. [u]
    B. [o]
    C. [a]

  5. ____ je orisi ihun silebu yoruba

  6. A. KF
    B. KN
    C. FK

  7. Oro-aropo-afarajoruko ni ____

  8. A. won
    B. yin
    C. emi

  9. "Ojoojumo ni oga n mu siga" 'n' je atoka iba isele

  10. A. aterere
    B. baraku
    C. aniyan

  11. "Iya agba pon omoomo re" je gbolohun

  12. A. alatenumo
    B. onibo
    C. abode

  13. "The job is energy sapping

  14. A. ise yii lagbara
    B. ise yii nilo agbara
    C. ise yii le run agbara eniyan

  15. Ki ni itufo?

  16. A. wiwe oku eniyan
    B. tite oku eniyan
    C. kikede iku enikan

  17. Oke ihin ko je ka ri oke ohun; a kii pa owe yii ni ile ____

  18. A. ana
    B. ore
    C. oga

  19. Eya je irin ise ____ ?

  20. A. alaro
    B. agbede
    C. ademu

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday