Saturday, May 26, 2018

Otunla, Ijeta Ati Idunta

Ki a to gunle iyato to wa laarin otunla, ijeta ati idunta_ o se pataki lati mo pe omo iya kan ni won on se nitori pe gbogbo won n toka akoko tabi igba ti ohun kan tabi isele kan waye.

Iyato ibe fara han lati ibi wi pe ona ti won gbe n toka akoko yato si ara won.

Otunla: Eyi ni a le pe ni ojo keta si ojo ti a wa yii. Awon oloyinbo maa n pe e ni (in three days time). Ninu akaba ojo tabi akoko, ola ni a maa kan ki a to kan otunla.
Apeere: Mo pinnu lati ba yin lo si ibe ni otunla.

Ijeta: Eyi ni a le pe ni ojo keta seyin ojo ti a wa yii. Oun ni a maa n pe ni (three days ago) ni ede geesi. Ana ni o tele ijeta, leyin ana ni o kan oni tabi ojo-oni.
Apeere: Nje awon omo naa pade ni ijeta?

Idunta: Eyi ni a le pe ni odun keta seyin odun ti a wa yii. (Three years ago) ni awon oloyinbo n pe e. Esi tabi odun-esi ni o tele idunta, leyin esi ni o kan odun ti a wa yii.
Apeere: Awa se idunta bee ni a se odun esi bakan naa ni a o se odun yii layo ati alaafia.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday