Friday, September 28, 2018

Ogun Jija Laye Atijo (Yoruba Ancient War)

Image from Google Search


  • Ohun ti o n fa ogun jija: Lara awon ohun ti o maa n mu ki ogun jija be sile lawujo Yoruba, laye atijo, ni a ti ri egun agbara awon alagbara, aala ile, ife lati konileru, ati bee lo.
  • Ipalemo ogun: Oba alaafin lo ni ase lati sigun si ilu miiran. Ki won to se eyi, won yoo bi ifa leere boya isigun oun ko ni ba ewu de. Leyin eyi ni awon eso omo-ogun yoo gbera lo soju ogun.
  • Awon omo ogun: Nile Yoruba, Oye ti oba ma fi n da akoni jajunjagun lola ni oye Aare Ona Kakanfo. Amo ti a ba n soro nigba orisirisi ipo awon omo ogun laye atijo nile Yoruba (Ancient Yoruba Military Ranks), Balogun ni ipo ti o ga ju. Balogun naa ni awon isomogbe tire. Seriki ni ipo ti o tele ti Balogun nigba ti Asiwaju je ipo ti o kangun si ipo Seriki. Leyin eyi ni Sarumi (awon omo-ogun ti o maa n fi esin ja).
  • Eto ogun jija: Ni owoowo ni won maa n to ja ogun ni oju-ogun (battle field) ni aye atijo. Awon to wa niwaju ni yoo koko sigun tira won ki awon ti o tele won to woya ija loju-ogun.
  • Ami: Ni awon omo-ogun ti n sise ajemotelemuye. Awon ni a n pe ni (spy) in ede Geesi. Won a mura bi ajeji lasan wo inu ilu ti won fe kogun ja lati fi ogbon mo ipalemo de ogun ti n bo lona.
  • Odi: Eyi ni ogiri giga ti a ko yi ilu po ki o le soro fun ilu miiran lati kogun ja ilu naa.
  • Yara: Eyi ni koto ti a wa yi odi-ilu ka ki o ma ba rorun fun ilu miiran lati kogun ja ilu naa.
  • Alore: Eyi ni awon omo-ogun ti o n so ibode ilu. Won a si ta ara ilu ni olobo bi won ba keefin ijamba tabi ikolu to n bo lona.


Tuesday, September 25, 2018

Apeere Awon Akanlo Ede Ati Itumo


E je ki a lo anfaani yii lati se agbeyewo die lara awon Akanlo Ede Pelu Itumo Won.

1. Ayírí: Eni ti ara re ko bale
2. Tiraka: Gbiyanju lati se nnkan.
3. Bònkélé: Nnkan ikoko, eyi ti o wa ni ipamo, asiri.
4. Háwó: Ni ahun, ma fe funni ni nnkan.
5. Faraya: Da ibinu sile.

6. Bá òkú wodò: Ohun ti ko le tete baje.
7. Fárígá: Ko jale lati gbo tabi gba.
8. Bá ni lórò: Gba eniyan ni imoran.
9. Gbèyìn bebo jé: Wuwa odale tabi dale ore.
10. Àgbàdo inú ìgò: Ohun ti apa eni ko le ka.
11. Ìtì ògèdè: Ohun ti ko se pataki.
12. Ajá olópàá: Eni ti o maa n se ofofo fun awon olopaa.
13. Àjànàkú sùn bí òkè: Ki eniyan nla kan lawujo ku.
14. Bí adìe dani lóògùn nù, a fó o léyin: Ki eniyan fi buburu gbesan buburu.
15. Ejò lówó nínú: Ki eniyan fura si enikan nipa isele kan.

Monday, September 17, 2018

Awo Oro (Yoruba Cleansing Ritual)


Ta Ni Olori Awo Oro?

Ninu asa ati ise Yoruba, Àjànà ni olori awo oro.

Bi o tile je pe awo ni oro, awon eya Yoruba kan mu un bi ayeye odun kan pato. Ni awon ibikan ni ipinle Oyo (Lanlate, Eruwa, Igboora, Idere, Ayete, Tapa ati Ibarapa) ayeye iranti awon baba-nla won ni won pe ni oro sise sugbon ni awon ibikan ni ipinle Ogun, awo ni oro. Eyi lo si faa ti won fi maa n so pe bi obinrin ba foju kan oro, oro yoo gbe e.

Ni awon adugbe ti won ti mu oro sise gege bi awo, iwonba eniyan perete ni o mo alude ati apade awo yii (eyi si yo awon omode ati awon ibinrin sile). Oselu, etutu ilu ati ato-ilu ni won maa n fi oro se nipa pe won maa n lo o lati dekun wagbo iwa ibaje bi ole jija laarin ilu bee won a si tun maa lo oro lati wa ju rere awon alale-ile tabi awon ibo to di ilu bee mu nipa gbigbe oro kaakiri inu ilu bee.

Saturday, September 15, 2018

Alamo

A Ya Aworan Yii Lati pulse.ng

Okan pataki lara ewi alohun ajemayeye ti a le ba pade lawujo awon Yoruba ni Alamo. Awon eya Ekiti maa n lo o nibi ayeye lorisirisi. Ewi yii wopo laarin awon ara Igbara-Odo, Ilawe, Ikere, Ita-Ogbolu, ati bee lo. Won maa n lo Alamo fun orisirisi ayeye bi igbeyawo, ikomojade, isile, ayeye oku-agba, ati bee lo.

Apere:
Ia nan me i pon ma ran
O tule A dile wode
A mo ko loni o
Oo woro ire oni mo ko, aworo
O kaatijo omo Olosun ona meji o,
Oo woro ire oni mo ko.
Osun kee nunu ile ji an bu toko,
Oo woro ire oni mo ko.
Mo rele o, oni ki mo ni
Moo jere
Omo dara tan
Omo Olure upona Oso bu o
O ni ki mo jere...

Friday, September 14, 2018

Isori Oro (Part of Speech)


Iru isori-oro wo lo wa ninu awon gbolohun yii?
i.) Ko si eni ti o gbon ayafi Olorun
ii.) N o fe ki e maa se bi dindinrin ni ibi yii
iii.) E je ki a ko ile giga kan

Gbankogbi okodoro oro ni wi pe a kii ri gbolohun ki a ma ri awon isori-oro fa yo ninu re.

Gbolohun ninu girama ede Yoruba ni ahunpo oro ti a n lo lati fi gbe ero okan jade. Ki gbolohun ma baa ruju ni o fi je knanpa tabi dandan fun akekoo ede Yoruba lati mo nipa awon eya awe-gbolohun lorisirisi.

Iro lo satokun fun oro; oro lo satokun fun isori-oro ninu eko girama ede Yoruba. Yoruba bo, wo ni bi eye ba se fo ni a oo se so oko re. Awon isori-oro ni a fi n hun gbolohun nitori pe ise ti oro ba se ninu gbolohun ni a le fi mo iru isori-oro ti n se. Odu ti kii saimo fun oloko ni isori-oro gbodo je fun ojulowo akekoo ede Yoruba. Die lara apere ni oro-oruko, oro-ise, ati bee lo.

Ninu awon gbolohun oke, ayewe-idanwo wo fala si abe awon oro yii: "Ayafi", "Je", "N", "Yii", "Dindinrin", "Giga", "Maa".

Ayafi = Oro-Asopo (conjunction)
N = Oro-Aropo Oruko eni kin-in-ni eyo ti o wa nipo oluwa (first person singular pronoun in subject form)
Maa = Atoka afikun oro-ise (auxiliary verb)
Dindinrin = Oro-Aponle (adverb)
Yii = Oro-Apejuwe Asafihan (demonstrative adjective or determiner)
Je = Oro-Ise (verb)
Giga = Oro-Apejuwe (adjective)

Tuesday, September 11, 2018

Akamo Ninu Girama Ede Yoruba


Okan pataki lara ohun amuye fun gbogbo ede lawujo omo alaaye ni a ti ri girama. Eyi si je okan lara isori ti a fi maa n da ede ti o ni igbekale ti o danto. Bi a ko ba gbagbe, a ti menu baa ri wi pe a le pin ede si imo-eda-ede, litireso, girama ati asa.

Ninu ise akanse ranpe yii, a oo toka si awon akamo ti a maa n ba pade ninu girama ede Yoruba. Awon akamo bii foniimu, biraketi, foonu ati colonu.

Akamo Foniimu ni ila-alakaba meji ti a maa n ba pade ninu eko fonoloji ati fonetiiki. A maa n lo lati fi adako iro alifabeti Yoruba (yala konsonanti tabi faweli). Apere ni /b/ /o/ ati bee lo.

Akamo Biraketi je akamo ti a le lo fun alifabeti, oro, apola, gbolohun. Nigba ti a ba n se ipin si isori ni a maa n lo akamo biraketi pelu alifabeti lati fi ya isori kan soto si omiran. Afikun itumo lo maa n sabaa mu ki a lo akamo biraketi pelu oro, apola tabi gbolohun. Apere ni (d) (egbon mi) ati bee lo.

Akamo Foonu fe fi ilo jo ti akamo foniimu nitori pe alifabeti nikan ni a maa n loo fun ninu eko nipa ato-iro ede. Apere ni [f] [t] [u] ati bee lo.

Monday, September 10, 2018

Ifa ati Eko Imo Ijinle Saikoloji


Psychology tabi eko imo ijinle saikoloji da lori bi ero-okan se n se atokun ihuwasi ohun abemi bii eniyan ati eranko.

Ninu akosile yii, a oo se agbeyewo ota nini lawujo eniyan ati iha ti eko ifa ati eko saikoloji ko sii.

Ota nini ti wa lawujo omo adarihurun lati igba ti oju wa lorokun. Ifa ati awon orisi ese ifa je ohun eri-maa-jemi ti a le lo lati fi gbe igbagbo wa lese wi pe ota nini ti wa tipe.

Ni ibamu pelu eko imo ijinla awon ojogbon ati onkotan Yoruba, a ti rii pe okan gboogi ise ota tabi awon ota ni gbigbogun tini bee si ni okan-o-jokan idi lo le sokunfa igbogun tini; lara won ni a ti ri inunibini, arankan, ilara, tembeleku, irenije, bamubamu-ni-mo-yo, ifigagbaga, ati bee bee lo.


Ifa ti o je okan pataki lara awon baba-nla Yoruba naa ko sai foju wina awon ota lorisirisi koda, awon eniyan gbogun tii, awon eleye gbogun tii , awon omo bibi inu re naa gbogun tii pelu; sugbon nipa agbara, ogbon atinuda, ati suuru ni ifa fi segun awon ota gege bi a se rii ka ninu awon akosile lorisirisi.

Apeere pataki ni ese ifa Ose Meji isale yii:
"...Ahere ni i sawo inu oko;
Okiti banba ni i sawo eba ona.
Emi ni n o o maa lekee won;
Fila ni i leke ori
Eni ni n o o leke otaa mi.
Akete ni i lekee fila;
Emi ni n o o leke otaa mi.
Aatan ni i leke ile;
Emi ni n o o leke otaa mi."

A oo rii wi pe ese ifa yii fi han gbangba pe Ifa (akere finu sogbon) ko sai lota laye bee si ni won fi n ye eni abiafun wi pe oun naa so leke awon ota re gege bi ifa se leke.

Lakotan, a ti rii wi pe a ko le ya ifa, ota nini ati omo bibi inu eniyan soto. Sugbon awon ogunagbongbo ninu eko adalori ihuwasi ati ero-okan eniyan (Professional Psychologists) ti fi han pe ni opo igba, eniyan ni ota ara re (Most instances, people are their own self-enemies).

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday