Friday, January 25, 2019

Ami Ohun Ati Apeere



Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii:
(1) Ohun isale
(2) Ohun aarin
(3) Ohun oke

Bi a ba n ko ede Yoruba sile, a maa n lo awon ami ohun lati ya awon ohun Yoruba wonyii soto. Fun apeere:
Ohun isale = ami ohun \
Ohun aarin = ami ohun -
Ohun oke    = ami ohun /

Lopolopo igba, o maa n wulo fun akekoo lati lo awon ami ohun orin ti a ko sisale wonyii lati ranti awon ami ohun Yoruba.
Ohun isale = ami ohun \ = d (do)
Ohun aarin = ami ohun - = r (re)
Ohun oke.   = ami ohun / = m (mi)

Ami ohun isale: (i) konko (dododo) (ii) asa (dodo) (iii) ojo (dodo) (iv) akalamagbo (dododododo)
Ami ohun aarin: (i) aso (rere) (ii) eran (rere) (iii) sobolo (rerere)
Ami ohun oke: (i) ranti (mimi) (ii) boya (mimi) (iii) lagbaja (mimimi)
Nje O Ti Ka:

1. Foniimu Faweli Ede Yoruba


Ila Kiko Nile Yoruba (Yoruba Tribal Marks)



“Aluwala olonginin, ogbon ati keran je ni”; asa ila kiko ni gbolohun yii n fi ogbon bawi nitori pe ogboogbon ni ila kiko gba di asa nile kaaro-o-jiire.

Orisirisi itan agboso ni o ro mo asa yii. Itan kan toka si I pea won eru nikan ni won n ko ila nile Yoruba laye atijo (awon eru oba). Amo sababi kan mu ki won fi ibinu ko ila fun eru kan gege bi ijiya fun ese re laimo pe ila ti a ko fun eru yii yoo mu un tubo rewa si i ni. Nigba ti ila naa ti so eru ohun di arewa ni oba naa ba pinnu pe oun  naa yoo ko irufe ila bee. Nigba ti oloola bere si ni ko ila fun oba, tiroratirora ni debi pe oba ohun ko le mara duro ko ila naa tan. Iru iwa yii lo bi owe Yoruba to so pe “Tita riro laa kola, amo ti o ba jinna tan nii doge”. Itan yii fi han pe bi ila kiko se di ohun amusoge lawujo awon Oduduwa niyen.

A si tun ri itan miiran to fi han pe nigba laelae, nile Yoruba, ogun ati ikonileru gbile bi owara-ojo; eyi si n ko orisirisi ipinya airotele ba awon ebi (bi ogun ati ikonileru se n ya oko ati iyawo, bee ni o n ya awon obi kuro lodo awon omo won). Eyi lo mu ki awon ebi kookan gunle orisi ila kiko gege bi ogbon idanimo ntori igbagbo Yoruba wi pe lojo eni ti o ku ati eni to sonu yoo pade ara won.

Nje ki wa ni awon idi ti Yoruba fi n ko ila? (i) fun idanimo (ii) fun oge sise (iii) fun igbelaruge asa Yoruba.

Orisirisi ni ila kiko ni ile Yoruba. Bee ni o si yato si ara won lati agbegbe kan si ekeji. Awon ila bi pele, abaja, baamu, abaja pelu baamu, gonbo, gonbo pelu baamu, keke, ture, ati bee lo ni won n ko nile Yoruba sugbon eya Yooba kookan ni o ni orisi ila tire.

Si tun se Pataki fun wa lati ranti pe eniyan ti o yan ise ila kiko laayo ni a n pe ni Oloola. Iru ise bayii si le je ajogunba tabi kiko lati inu ebi to yan an laayo.
Nje O Ti Ka:

Iro Ohun ati Ami Ohun (Yoruba Tonal Sounds and Signs)


Ifa ati Eko Imo Ijinle Saikoloji


Itoju Ara Ati Ayika (Cleanliness)



Lati le dena arun ati aisan ni imototo fi se Pataki. Ona ti a si n gba ni imototo ni ki a se itoju ara ati ayika.
1.       Iwe wiwe wa lara ipa ti eniyan maa n ko lati toju ara. Ki a fi ose ati kan-in-kan-in ti o dara pelu girisi (ipara) fun ara ni ewa ti o ye.
2.       Eyin fifo se Pataki fun enikeni to ba few a ni imototo. Eyi se Pataki loorekoore nigba ti eniyan ba ji lowuro ati nigba ti eniyan ba fe lo sun. Burosi tabi pako irunyin ni a fi n foe yin mo.
3.       Itoju irun-ori ti wa lati igba laelae titi di oni; tokunrin tobinrin lo si maa n toju irun. Awon obinrin gbodo se irun ni kiko tabi ni didi nigba ti awon obinrin maa n ge irun won . O tun je kannpa lati maa fi omi ati ose fo irun wa.
4.       Itoju eekanna owo ati eekanna ese nipa ki a maa ge won, ki a si maa fo won lati dekun idoti to fe tabi to le farapamo sisun awon eekanna wa.
5.       Itoju aso o gbeyin ninu akitiyan lati dena arun to le kolu ara nipa ki eniyan ma wa ni imototo. Nse ni a gbodo maa fo awon aso wa pelu ose ati omi to mo.
6.       Itoju ayika (yala_ ile-igbe, ile-eko, ile-ise, tabi oja) se Pataki bakan naa. Eyi ni ko ni je ki eniyan je oye adara-lode-ma-dara-nile tabi adara-nile-ma-dara-lode. Lojoojumo ni o ye ki a maa fi igbale gba gbogbo ayika wa. A sit un gbodo maa gbon gbogbo panti ati jankariwo to so mo ile. A gbodo sa gbogbo agolo, igo-afoku, ewe ati ora tabi ohunkohun to le ko ijamba ba eniyan. A gbodo maa gba, ki a si tun maa fo oju gota ati oju-ona agbara, ki a si tun di awon ibi ti salanga ba ti fo lati dena arun ti eniyan le ko lati ipase oorun buruku. A gbodo maa se itoju ti o ye fun awon ile-iwe, ile-igbonse ati ati ayika idana. A gbodo maa ro awon oko ayika, ki a sit un ko gbogbo ohun ti ejo, efon, akeekee ati eku le farapamo si se eniyan ni ijamba jina si ayika ileegbe.
Ise imototo ko yo enikeni sile; ijoba, elegbejegbe,odo adugbo nitori pe agbajowo ni a fi n soya.
Nje O Ranti :

1. Orisirisi Oro-Ise 2

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday