Tuesday, May 29, 2018

Oju-Owo, Ere Ati Okuta

Ninu eko adalori kara-kata ni a ti saba maa n ba awon oro wonyi pade. O tumo si wi pe inu opon-ifa owo sise ni a ti i lo won. 

Oju-owo: Eyi ni owo ti onisowo (ti a tun mo si ontaja) ko jo lati fi bere owo ni sise; awon oloyinbo maa n pe e ni Principal.

 Gbogbo oro ninu ede yoruba lo ni owe tabi asayan oro ti a maa n lo pelu e. Eyi lo fa a ti eniyan le fi toka si ohun to niyi gege bi ohun to ka oju-owo. (Apeere: ebun naa ka oju-owo).

 Ere: Yoruba maa n pa a lowe pe "ere ni obinrin n je labo oja". Kin ni ere? Ere ni owo ti ontaja pa kun oju-owo leyin ti o ta oja re tan; a maa n pe ere ni "profit" tabi "gain" ni ede Geesi.

Eyi je idi pataki ti awon eniyan fi maa n sowo_ won a se owo ki won le ri apakun owo, won a se owo ki won le ta atajere.

Ojuta: A le pe okuta ni aseeeri ti o waye ninu owo sise tabi oja tita. Awon eniyan tun maa n pe e ni airere je. Ki Eledumare, Oba Adarihurun, ma se je ki a ba okuta pade nile aye; ase o. Kin wa ni a le pe okuta ni ede Geesi? Oun ni a n pe ni "loss". Okuta o dara.

Eyi lo fa a ti onisowo fi maa n ja fitafita lati ri oju-owo ko jo bi ogbon ati je ere ba doju de.

 Bi eniyan ba se owo tabi ta oja laarin ojo kan, o rorun fun iru eni bee lati mo boya oun ti je ere tabi oun ti ba okuta pade.

Sugbon ninu isowo ti yoo gba ontaja ni opolopo osu tabi opolopo odun, o se pataki fun ontaja lati ni iwe akosile owo to gun rege_ iyen "proper bookkeeping" ni ede Geesi lati le je ki o rorun fun ontaja nigba ti o ba n se isiro oja re.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday