Sunday, June 3, 2018

Olomoge

Olómoge tí n se fújà
Tétí kí o gbo ohun tí mo fé so fún o
Òpò ló ti soge bóge lo
Òpò lako ti lò mógbà
Ti wón wá gbó sása bí i aso
Ó dàgbèrè ìlú-mò-ón ká
Ti dúdú, ti pupa lò n bóra fun
Gbogbo ako ló mó ní pópó
Bí wón bá so e dako ajá tán
Tó o wá dàgbébò adìe
Ta ló fé gbé o sílé bí aya
Bó o bá bùrìn bùrìn
Bó o róko gbé o sílé
Ó pé, ó yá
Oko á bólómo lo
Olóbó kì í bímo
Àgbàtó ni wón fi n somo
Òwò tí kò pé
Òun lòwò àgbèrè
Ikú òjijì ló n bá tage
Éèdì, àtàtòsí ègbe
Lèrè eni n sòwò àgbèrè

(eni tó ewì yìí ni: Yèkínì Olátáyò.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday