Sunday, June 10, 2018

Orisa Sango



Yoruba maa n pa a lowe pe “eni ti Sango toju e wole, kii bawon pe e loba koso”
Sango je okan pataki ninu awon orisa nile Yoruba. Eyi losi fa a ti a fi maa n ri awon olusin Sango kaakiri ile kaaro-o-jiire. Sango ni a n pe ni ina-loju-ina-lenu (Afina fohun bi o ba soro), olukoso oko Oya.
Bi gbogbo orisa nile Yoruba se ni ojubo tiwon naa ni Sango ni ojubo tire. A si le ba asa ti a n pe ni Sango-Pipe ni awon ajodun ibile Sango, nibi oro Sango (eyi ni ibi ti awon adosu Sango ti se oro lati yo edun tabi oko ti Sango fi pa eniyan ladugbo kan), ati nibi eto isinku adosu Sango kan. Ona Mogba ni a n pe bale fun awon adosu Sango ni adugbo kan nitori pe orisirisi adugbo ni a le ba pade lawujo Yoruba.

Ti a ba n soro nipa Sango Pipe gege bi asa, oriki Sango ni eyi maa n ko sodi. Awon adosu Sango (yala lokunrin tabi lobinrin) lo maa n pe Sango bi o tile je pe awon obinrin lo sabaa maa n pe e, sibe ko yo awon okunrin naa sile. Ilana lile ati gbigbe ni won maa n lo lati fi pe Sango.
Apeere:-
Ayanrin ina
Olukoso Oko Oya
Ajala Iji, Ewelere, Ajija ote
Aara bowo ija lala
Ina gori ile feju
Iku tii pani tenikan o le mu
Sango, ma bami ja
No lowo ebo nile
Olubanbi, Ewelere mo sipe o
Ija a re gan-an oran
 Iku tii pani t’enikan kii ke
Afose yoni loju
Afedun yofun
Afeefin se ni pele
Afina fohun bi o ba soro.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday