Thursday, June 14, 2018

Ede Yoruba ati Oloogbe Adebayo Faleti


Oloogbe Adebayo Faleti je gbajumo osere ati onkotan lede Yoruba. 

Faleti, ti a bi lojo kerindinlogbon, osu kejila, odun 1921, je alakitiyan eniyan ti kii fi idagbasoke awujo Yoruba sere rara; yato si wi pe o je okan lara awon asaaju ninu ise ikaroyin ede Yoruba lori ero amohunmaworan lorilede Naijiria.
Bi o tile je pe awon ise takuntakun ti Adebayo Faleti gbe se lori igbende ati idagbasoke ere ori itage lori ero mohunmaworan ko see foju fo, amo ohun to je mi logun nihin ni ijinle ogbon atinuda ti Adebayo Faleti maa n lo lati fi se agbekale ewi re.

Okan lara ewi Oloogbe Adebayo Faleti ti mo feran ju ni “Ojo Ilayefun”; ewi ti Oloogbe Faleti ko lati fi maa ran wa leti pe o ye ki ore rere maa bo asiri ore re nibi gbogbo ati nigba gbogbo.

Ojo Ilayefun

Oniruuru ore la n ni:
Ore ire, ore ika;
Oto lore dabe-n-yanko,
Oto lore onibaje eniyan.
Kii se poree tooto ko si laye
Ibi ti won wa la o mo.
Sugbon won m be laarin kookan
Bi olomosikata ti wa laarin agbado
Nigba kan, igba kan
Niluu kan ti won n pe l’Asunnara,
Awon meji kan m be nibe, won n sore.
Ekini n je Sangodokun,
Ekeji si n je Laala;
Sangodokun ti niyawo ona,
Laala sese m b’Olodumare ni
Igba ti yo bu se gada, ti yob u se gede
Ni Sangodokun ba ko lugbona ode
Sangodokun dalaganna eniyan
O deni ti n sinwin kagbo ile kiri.
Bee ni won ko je ki ana re o gbo,
Ko ma waa dabi laifi leyin ola.
Ko ma dohun tii doju tini.
Ni won ba tete ro sekeseke meji
Won ko o sese Sangodokun,
Nitori bo ba n se were,
Ko ma dohun tipa ko nii le ka mo.
Won ko sekeseke sese tan
Won tun n fi patie soko fun un.
Bee Iyawo ku si dedede,
Iyawo re sese to o gbe ni,
Ki jannajanna to o gbara.
Laala ore re se kisa nibe
Igba to ya gbogbo re ro pese
Aisan-an were naa san fun Sangodokun.
Gbogbo ara ile re wa n yo sese
Pe were o si mo ninu iran awon.
Igba talaafia ti de fun Sangodokun,
To n sohun to ba ti gbogbo aye mu
Won ni ko gbewu wok o wa rele ana e.
(Se won so fun won po ti rebi ni).
Ni Sangodokun ba gbewu wo
Ni Laala ba mura, o gba tore e gerere.
Igba ti won dele ana re nko?
Gbogbo eniyan n yo fere,
Inu won dun pe won tun roko ape awon_
 Erin gbereke alatona, onigbowo pelu
Erin gbenu afesona Sangodokun.
Se won ko mohun to ti sele
Won de lati eyin-odi ni
Won ba yara madie opipi
Won yara lo madie osoro,
Won ti yara tami ape.
Won sare wonlubo kale gerere,
Won gbe e sinu igba niyara okankan
Ko jinna sibi won teni si fun Sangodokun,
Toun ati Laala feyin ti,
Ti won rogboku bi oba kotonkan.
Omi oka sese n fe ho ni ile idana
Baba omo, iya ati ara odede
Ni won n ro kukukeke
Ki won le tete gbounje falejo to bodale
Awon meji pere lo wa ku lodede
Laala pelu Sangodokun ni.
Igba o ya, Laala loun o to leekule,
O ba won nibi ina dida, o yanu.
Igba ti Laala yoo fi to tan, omi ho lori ina.
Iyayawo ku fiiri wole lati buyefun
Igba to wole ko ri Dokun
O woyara okankan ti won gbelubo si
Ibe niya iyawo ti ba Sangodokun
Ti n jelubo ekuku bi agutan,
Ti n lanu bi ewure jewe ata.
Iyefun to tip o nile kitikiti
Eyi toko iyawo la ku, ko kunwo!   
Iya iyawo kandi, ko mohun to le se;
O peyin da, o fe lo so fawon teekule
Loun Laala ba kora peki ni gbangba.
O ni, “Jowo, ore oko iyawo,
O o wa wohun toree re n se:
Elubo ta a bar o lamala
Loko iyawo ti fere je tan niyara”
Ologbon ni Laala, oloye ni,
O ti mo paaganna lo tun ko lore oun.
Ko woke to fi mudaahun wa,
O ni, “Abi awa le n dana fun?
Bi e ba wi ni, a ba ti je ki e dana
Nitori oni l’Ojo Ilayefun nile wa.
A ko gbodo je amala rara,
Bi a ba ti layefun ka mumi sii ni.”
Ni Laala ba bo sibi ti Dokun wa,
O bere si idi elubo, oun paapaa n layefun.
Niya iyawo ba n sipe pe ki won dakun,
Oun o tete mo ponii l’Ojo Ilayefun nle won.
Atiyawo ona, ati baba, atara ile,
Ni won jade wa woun ti n sele loode won.
Won ba Laala, won ba Sangodokun
(Won ti jelubo ekuku tan, igba e lo ku)
Won n fenu lagba bi olorikunkun eran.
Niya iyawo ba wa kejo kale, lo salaye
Pe lonii l’Ojo Ilayefun nile won
Ni gbogbo eniyan ba n se “Haa! A o mo!
E ma biinu, e fori ji wa, e dakun.”
Ni won ba n sure bomi mimu fun won.
Laala jelubo tan, o mumi, ikun wu banku
Lai-je-were, lai-tile-jasinwin
Sebi nitori kasiiri ore o le bo nile ana ni.
Asiri si bo titi won fi kuro nibe:
Awon ana sebi odun nla l’Ojo Ilayefun.
Awon mejeeji jelubo ekuku tan
Won ba mura o dadugbo won.
Won dele ni Laala wa kejo kale lo royin.
Ni won ba n dupe, won n sadua fun un
Funtiju to fi ba Sango layefun.
Won ba wa tun nawo gan Sangodokun
Won de e ni sekeseke lese.
Won poloogun nla to le rerun naa wo
Ko ba won le arun naa lo patapata.
  

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday