(1) Iran Kin-in-ni: Sola ati Kunbi pade Femi nigba ti won n rin lo ninu ogba Yunifasi. Femi beere ona gbogan ere idaraya, Sola si mu un lo ibe awon mejeeji si ti ipase eyi di ore wolewode.
(2) Iran Keji: Ori ironu ni baba Sola (iyen Kola Egbeda) wa nigba ti iyawo re wole de, o si fi oko re lokan bale lori gbogbo ohun ti n dun un lokan. Kop e lale ojo naa ni Sola de lati ile-iwe lati wa beere fun owo ise asetilewa egberun marun-un naira (N5000). Ebe Egbeda je, won mu lale ojo naa, won si lo sun; Iya Sola si la ala buburu kan.
(3) Iran Keta: Kunbi lo sile, o ba baba re ti n gbafe ninu agbala nla ile won to rewa ringindin. O beere owo lowo baba re, baba re ko besu begba ti o fi fun un ni ohun ti o n fe bi o tile je pe ko kunle ki baba re nigba ti o wole gege bi o ti ye ki ojulowo omo Yoruba ti o gbekoo se ki agbalagba. Eyi lo mu ki Nura (omo-odo awon Kunbi) ati Asogba bere si ni sapejuwe Kunbi gege bi alailekoole, oninakuna, olojukokoro, ati oniwokuwo omo.
(4) Iran Kerin: Kunbi ati Sola, ore re, wa ninu yara won ninu ogba Yunifasiti. Kunbi n ba Sola ro ejo amo Sola n fi ogboogbon ka iwe re bi se n takuroso. Won soro kan Femi; Kunbi si n je ki o ye Sola pe oun ko gba ti Femi rara nitori pe olowo ni oun maa n ta si amo sibe, Sola feran Femi pupo.
(5) Iran Karun-un: Femi so nipa Sola fun awon obi re. Eyi mu ki inu awon obi Femi tubo dun sii nitori pe won ti n reti ki Femi pinnu lati fe omobinrin miiran leyin ti Titilayo (iyawo re akoko) ti ku. Awon obi Femi tubo ki Femi laya pe awon fowo sii. Eyi mu ki Femi pinnu lati da enu ife ko Sola ati wi pe oun yoo feran lati fi Sola se iyawo oun.
No comments:
Post a Comment