Friday, December 21, 2018

Ore Mi lati owo Aderibigbe Morohunmubo (iran 6-10)


(6) Iran Kefa: Ni iran yii ni a ti ri Femi ati Sola ti won lo wo sinnima “Taxi Driver” ti Ade Love se. Ni gbara ti won kuro ni sinnima, won gba ile ounje lo nibi ti Femi ti so fun Sola pe oun feran lati fi se iyawo oun; oro won si wo.

(7) Iran Keje: Ni iran yii ni a ti fi han pe Femi kii se akuse (omo Oloye Odunwo nii se). Nigba ti Kunbi mo eyi, o bere si ni ke abamo wi pe kani oun ti mo ni oun o ba ti mu Femi lore. Lati igba yii ni o ti n da orisirisi ogbon lati fa oju Femi mora.

(8) Iran Kejo: Sola n se ipalemo fun sise agunbaniro. Eyi ati awon ohun miiran ni iran kejo dale.

(9) Iran Kesan-an: Awon obi Femi ati obi Sola mo ara won, won si tibe mu ojo igbeyawo.

(10) Iran Kewaa: Femi pa ni dandan fun Sola lati dekun sise ore pelu Kunbi nitori awon iwa agabangebe ti o kun owo re. Eyi ati awon isele miiran ni iran kewaa dale.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday