Orisirisi esin loti wo awujo awa Yoruba; eyi tio yato si esin abalaye.
1. Esin Musulumi eyi ti awon larubawa mu wo ile yi ni pa owo ati ogun jihaadi. Kurani ni iwe mimo ti won maa nka nigbati ile keu je ibi awon omode won ti maa bere eto Kurani mosalasi si ni awon Musulumi ti maa n jo sin.
Lara odun ti won maa n se ni (1) odun Ileya (odun ti a fi agbo dipo Summaila fun Buraimo) (2) odun itunu awe (odun ti won yoo gba awe ogbon ojo ninu osu Ramadani) (3) Odun Ijira (odun to je ibeere onka odun Musulumi) (4) ojo ibi anabi
2. Esin Kirisiteni eyi ti awon oyibo mu mo ile Yoruba nipa owo sise ati ijinrere. Soosi ni won ti maa n josin. Bibeli si ni won maa nlo. Lara odun ti won maa n se ni (1) Keresimesi (odun to jemo ojo ibi jesu Kristi eyi to maa waye ninu osu ope) (2) Odun Ajinde (eyi ti o fi rapada ti Jesu fun gbogbo eda eniyan han)
3. Esin Gurumaraji eyi ti o gbagbo wipe ohun ni Mesaya ti gbogbo aye n reti. Pupa ni awon olusin yii maa feran lato wo, won si feran odo pupa.
4. Esin Ekanka; awon yii ni okan won maa n rin irinajo. Won gbagbo pe ile ile aye je ile eko nitori naa ninu irin ajo won ni won yoo ti maa keko laye.
No comments:
Post a Comment