Ere idaraya le je ti gbangba tabi ti abe – ile. Ona meji ni a le pin ere idaraya si:
(1) Ere osupa (2) Ere ojumoomo
Ere osupa ni ere idaraya laarin awon ewe ti o maa n saba waye nigba ti ile ba ti su, sugbon ti osupa mole. Lara awon ere osupa ni Ekunmeran, Bojuboju, Ta lo ga ju laba;gbogbo awon ere wonyi je ti gbangba. Awon ere osupa ti o je ti abele ni a ti ri alo apamo ati alo apagbe.
Ere ojumoomo ni awon ere idaraya ti o maa n waye nigba ti ile koi su. Awon ere bi Ekunmeran, Bojuboju, Ta lo ga ju laba, ijakadi; awon wonyi je mo ita gbangba nigba awon ere bi ayo tita, okoto tita, ogo tita, awon ere wonyi je mo abe ile.
Awon ere ita gbangba maa n fun eniyan lokun ati agbara nigba ti awon ere abe ile maa n fun eniyan ni ironujinle ati iriri to gbooro sii.
No comments:
Post a Comment