Kokoro Salamo (Dinosaur Ant) je irufe kokoro kan ti eya re ko fi taratara wopo ninu ipin si isori awon kokoro. Kokoro yii ni awon onimo sayensi (scientists) n pe ni Notomimesia (Nothomyrmecia) ti a tun le pe ni (dinosaur ant) tabi (dawn ant) lede Geesi.
Ninu awon kokoro yooku, oun nikan ni awo re pupa feerefe bi ti epo-oyin (sweet honey), idi abajo si ni wi pe ohun ti o ba dun ni o maa n la_ fun apeere (oyin, osan, mongoro, iyeye, ati bee lo).
Ori igi ni kokoro salamo n gbe_ igi mongoro, igi osan, igi iyeye ati bee ko. Lara awon abuda (characteristics) miiran ti o ni ni a ti ri tita itakun (nesty cocoon) yi eyin re ka bi ti alantakun (spider). Abuda mii ni sisu bo eniyan lati ge eniyan je amo tita re kii dun eeyan to ti kokoro tanpepe, kokoro kaninkain tabi kokoro ikamudu. Abuda miiran ni pe kokoro salamo kii yara to awon kokoro bi tanpepe bee si ni kokoro salamo maa sabaa gbagbe ara re si oju kan bi ohun ti o ti ganpa.
Kokoro yii wopo ni Afirika ati orilede Osirelia ati awon agbegbe re.
Kaa Siwaju Sii>>>
Kaa Siwaju Sii>>>
No comments:
Post a Comment