Akiyesi ti fi han gbangba pe awon akekoo maa n gbe alaye oro mejeeji yii funra won. Eyi lo fa a ti a fi pinnu pe ki a to toka si ohun ti o mu gbolohun onibo yato si awe-gbolohun afibo, a oo koko ran a leti oriki gbolohun ati awe-gbolohun.
Ki ni gbolohun? Gholohun ni akojopo oro ti a n lo lati fi gbe ero okan jade ni ibamu pelu ofin isowo-lo-ede. Orisirisi ona ni a le gba pin gbolohun ede Yoruba nipa fifi oju ihun, ilo, tabi iye oro-ise wo o.
Ki ni awe-gbolohun? Eyi je okan lara koko oro ti a le ri fayo lati inu gbolohun olopo oro-ise. Ninu Gbolohun olopo oro-ise, a maa n ri olori awe-gbohun ati awe-gbolohun afarahe.
Ki ni Gbolohun Onibo? Eyi je okan lara awon gbolohun olopo oro-ise ti a fi gbolohun kan bo inu gbolohun miiran. A maa n lo awon atoka-afikun bi “pe”, “ki”, “lati” lati fi saaju gbolohun ti a fi bo inu gbolohun mii. Apeere: A gbagbo pe iku ni ere ese.
Alaye Yi Kun
ReplyDelete