Okan lara ohun ti o n toka asa ni ounje. Bi a se ni awon ounje ti a le pe ni ti gbogoogbo bee naa ni a ni eyi tii se ti awon Yoruba ponmbele. Kannpa ni ounje fun gbogbo omo adarihurun, eyi lo si fa a ti a fi ni orisirisi owe ajemo ounje nile Yoruba. Owe kan so pe ohun ti eye ba je ni eye n gbe rorun.
Wiwa laaye ati laye eniyan ro mo ounje ti eniyan ba n je. Awon ounje afunni lokun wa, bee naa ni awon ounje amaradan naa wa pelu, eyi lo mu awon Yoruba maa so wi pe ounje lore awo.
Bi o se ti je wi pea won omo Yoruba ko si ni oju kan naa mo, awon kan wa ni Ile-Ife, awon kan wa ni Oye Ekiti, bee sin i awon miiran wa ni Akoko ni ipinle Ondo. Lara ohun adamo fun okookan awon orisirisi ilu nile Yoruba ni ounje wa.
Eyi tumo si wi pe ounje ti o wopo laarin awon eya Yoruba se otooto fun apeere adalu, ebiripo, ifokore, ati bee lo; lo wopo laarin awon Ijebu nigba ti amala-lafun wopo laarin awon Ibadan.
Nipase olaju, orisirisi awon ounje ajeji tabi atohunrinwa lo ti wo orilede Naijiria ti o si ti dapo mo awon ounje ti a mo ni ti eya Yoruba.
No comments:
Post a Comment