Saturday, November 17, 2018

Aroko Asapejuwe (Ebi Ogbeni Ajayi)


Oruko mi ni Ade Ajayi bee ni mo si je omodekunrin lati ile adulawo, Afirika. Mo n gbe pelu baba mi, iya mi, awon aburo mi lokunrin ati lobinrin. Iyaaya mi ati iya-baba mi n gbe pelu wa bakan naa. Lai fa oro gun, ebi Ogbeni Ajayi ko ju bayii lo.

A n gbe ninu ile ti baba mi ko. Eyi wa ni okan lara awon ileto ti eniyan le ba pade ni Iwo-Oorun Afirika.



Emi ko ga pupo nitori pe mi ko ju omo odun mokanla pere lo. Awon aburo mi lokunrin ati lobinrin keere pelu. Amo awon obi mi ko reere lojo-ori. Ki gan-an lojo-ori won? Emi ko mo. Baba mi ti ju omo odun marundinlogoji sugbon o se e se ki iya mi je omo ogbon odun.

Ni idakeji ewe, awon obi ti o tuko obi mi wale aye ti di arugbo; won yoo ti pe omo aadorin odun. Amo n ko le fogun re gba ori.

No comments:

Post a Comment

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday