Ninu eko adalori kara-kata ni a ti saba maa n ba awon oro wonyi pade. O tumo si wi pe inu opon-ifa owo sise ni a ti i lo won.
Oju-owo: Eyi ni owo ti onisowo (ti a tun mo si ontaja) ko jo lati fi bere owo ni sise; awon oloyinbo maa n pe e ni Principal.
Gbogbo oro ninu ede yoruba lo ni owe tabi asayan oro ti a maa n lo pelu e. Eyi lo fa a ti eniyan le fi toka si ohun to niyi gege bi ohun to ka oju-owo. (Apeere: ebun naa ka oju-owo).
Ere: Yoruba maa n pa a lowe pe "ere ni obinrin n je labo oja". Kin ni ere? Ere ni owo ti ontaja pa kun oju-owo leyin ti o ta oja re tan; a maa n pe ere ni "profit" tabi "gain" ni ede Geesi.
Eyi je idi pataki ti awon eniyan fi maa n sowo_ won a se owo ki won le ri apakun owo, won a se owo ki won le ta atajere.
Ojuta: A le pe okuta ni aseeeri ti o waye ninu owo sise tabi oja tita. Awon eniyan tun maa n pe e ni airere je. Ki Eledumare, Oba Adarihurun, ma se je ki a ba okuta pade nile aye; ase o. Kin wa ni a le pe okuta ni ede Geesi? Oun ni a n pe ni "loss". Okuta o dara.
Eyi lo fa a ti onisowo fi maa n ja fitafita lati ri oju-owo ko jo bi ogbon ati je ere ba doju de.
Bi eniyan ba se owo tabi ta oja laarin ojo kan, o rorun fun iru eni bee lati mo boya oun ti je ere tabi oun ti ba okuta pade.
Sugbon ninu isowo ti yoo gba ontaja ni opolopo osu tabi opolopo odun, o se pataki fun ontaja lati ni iwe akosile owo to gun rege_ iyen "proper bookkeeping" ni ede Geesi lati le je ki o rorun fun ontaja nigba ti o ba n se isiro oja re.
Tuesday, May 29, 2018
Saturday, May 26, 2018
Otunla, Ijeta Ati Idunta
Ki a to gunle iyato to wa laarin otunla, ijeta ati idunta_ o se pataki lati mo pe omo iya kan ni won on se nitori pe gbogbo won n toka akoko tabi igba ti ohun kan tabi isele kan waye.
Iyato ibe fara han lati ibi wi pe ona ti won gbe n toka akoko yato si ara won.
Otunla: Eyi ni a le pe ni ojo keta si ojo ti a wa yii. Awon oloyinbo maa n pe e ni (in three days time). Ninu akaba ojo tabi akoko, ola ni a maa kan ki a to kan otunla.
Apeere: Mo pinnu lati ba yin lo si ibe ni otunla.
Ijeta: Eyi ni a le pe ni ojo keta seyin ojo ti a wa yii. Oun ni a maa n pe ni (three days ago) ni ede geesi. Ana ni o tele ijeta, leyin ana ni o kan oni tabi ojo-oni.
Apeere: Nje awon omo naa pade ni ijeta?
Idunta: Eyi ni a le pe ni odun keta seyin odun ti a wa yii. (Three years ago) ni awon oloyinbo n pe e. Esi tabi odun-esi ni o tele idunta, leyin esi ni o kan odun ti a wa yii.
Apeere: Awa se idunta bee ni a se odun esi bakan naa ni a o se odun yii layo ati alaafia.

Sunday, May 13, 2018
Awe-Gbolohun Afibo Ati Awe-Gbolohun Asapejuwe
Awe-gbolohun afibo ati Awe-gbolohun asapejuwe
A ti mo wi pe ni abo fun odindi gbolohun yala o le da duro tabi ko le da duro.
Bi a ba wo ibasepo to wa laarin awe-gbolohun afibo ati awe-gbolohun asapejuwe, a le fowo soya pe awe-gbolohun asapejuwe ni awe-gbolohun afibo ti o n sise eyan ninu gbolohun ede Yoruba.
Apeere:
Ajiboye gba pe ounje gidi ni iyan (awe-gbolohun afibo)
Ile ti Ade ko ti wo lana (awe-gbolohun asapejuwe).
Friday, May 4, 2018
Subscribe to:
Posts (Atom)
Ami Ohun Ati Apeere
Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...
Word of the Day
Word of the Day
provided by TheFreeDictionary.com
Quote of the Day
Quote of the Day
provided by TheFreeDictionary.com
Article of the Day
Article of the Day
provided by TheFreeDictionary.com
This Day in History
This Day in History
provided by TheFreeDictionary.com
Today's Birthday
Today's Birthday
provided by TheFreeDictionary.com
Today's Holiday
Today's Holiday
provided by TheFreeDictionary.com
-
“Aluwala olonginin, ogbon ati keran je ni”; asa ila kiko ni gbolohun yii n fi ogbon bawi nitori pe ogboogbon ni ila kiko gba di asa nile kaa...
-
Kari aye ni oro iku; bee si ni oje ase Eledumare fun gbogbo ohun ti o da, ko si eniyan ti o mo iru iku ti yoo pa ohun tabi ibi ti iru iku be...