ORE MI LATI OWO ADERIBIGBE MOROHUNMUBO M.
Iwe itan “Ore Mi” je ere onise ti Aderibigbe Morohunmubo se akosile re. Ere onise yii da lori ife ati ore nini.
Ahunpo itan naa fi han pe ore meji kan wa (Sola ati Kunbi); won n ba ore won bon ni ogba yunifasiti. Sola je obinrin to rewa, omoluabi ati ore rere si Kunbi sugbon Kunbi je obinrin to rewa, alailekoo, oniwokuwo, olojukokoro, ati ore buruku si Sola.
Omo atapatadide ni Sola, awon obi re maa n sasokesasodo ki won to le ri owo jeun ati owo ile-iwe Sola. Ni idakeji ewe, omo onile-olona ni Kunbi, inu owo ni won bii si.
Bi o tile je pe inu owo ni a bi Kunbi si, ko si ohun ti o maa n te e lorun nitori akebaje omo nii se. Iwa ojukokoro re lo mu ki o fi oogun gba oko Sola, ore re. Yoruba bo, won ni, bi iro ba lo fun ogun odun, ojo kan bayii ni otito yoo ba a. laipe ojo, oogun sunko, ewe si baje; oju Femi ‘oko Sola’ la kedere, o si han sii kedere pe oun ti fi aimokan fi Sola, ololufe re, sile lati maa fe Kunbi.
Ika pa onika nitori pe Kunbi ko esan iwa odale re, se ni o ya weere.
No comments:
Post a Comment