O se Pataki ki a mo wipe aroko ariyanjiyan gbodo tele akoko ode – oni. Ede tabi Yoruba ajumolo se Pataki ninu kiko aroko yii. Lilo awon ewa – ede bii owe, akanlo ede, afiwe ati bee lo se Pataki.
Aroko gbodo ni ilapa – ero, ninu ilapa ero ni a ti ri ifaara, koto inu aroko ati iwadii.
Ninu iwadi ni a ti maa n saba fi ti ko oro gunle.
Aroko alariyanjiyan je ona ti a n gba gbe ero totun – tosi kale, tii a si wadi ero naa nipa fifi ero eni han lori koko ero bee. Ona meji ni a le gba gbe aroko yii kale.
A le koko so ero wa si otun naa ki a to wa so si osi. Ni ona keji, a le so si otun, ki a tun so si osi. Ohun ti o se Pataki ninu aroko alariyanjiyan ni wi pe a ko gbodo dari apa kan fi kan sile.
No comments:
Post a Comment