Ni aye atijo, awon Yoruba kii foju kere ajosepo idi niyi ti won fi ma n pa owe pe “ki arin ki a po, yiye nii yeni”, “Ajeji owo kan ko gbe eru dori”
Yoruba ni awon ona iran ra eni lowo lorisirisi lara won ni:
(1) Arokodoko
(2) Owe
(3) Aaro
(4) Ebese
E je ki ase ayewo awon ona iran-ra-eni-lowo wonyi leyokookan.
(1) Arokodoko: je asa iran-ra-eni-lowo ti o maa nwaye laarin eniyan meji ti oko won fegbekegbe. Nigba ti won ba ti gunle ona yii, ojo kan na ni awon mejeeji yoo fi oko riro si, ti awon mejeeji yoo si maa roko wo inu ara won.
(2) Aaro: le waye laarin okunrin tabi obinrin. Awon ti won ba ni agbara bakan naa ni won maa da aaro nitoripe eyi ko fi aye gba iwa ole. Won yo ma se eyi lati odo eni kan ti yoo fi kari gbogboawon elegbe aaro.
(3) Owe: je iran-ra-eni-lowo ti Yoruba maa n ka si ara idana iyawo. Awon ebi ati ore ni a maa n saba be ni owe. Aaro kutukutu ni won maa bere ise owe, eyi tio si ni sisan pada.
(4) Ebese: ni ama nlo lati fi ran eni ti o ni ailera, idiwo Pataki tabi irin-ajo Pataki. Gege bi owe, ebese je ohun ti a kii san pada, bee, awon ebi ati ore ni o ma n saba se eyi.
Esusu ati san-die-die nko?
ReplyDelete