Orisirisi aroko ni o wa ninu eko ede Yoruba; okan lara won ni aroko asapejuwe ti o ro mo akori ti a oo maa se agbeyewo re.
Eyi ni awon koko ti akekoo gbodo tele bi o ba fe ko aroko ti o yanranti lori "Ayeye Isile Kan To Soju Mi"
1. Adugbo wo ni ayeye isile naa ti waye? Ilu wo ni?
Eyi ni awon koko ti akekoo gbodo tele bi o ba fe ko aroko ti o yanranti lori "Ayeye Isile Kan To Soju Mi"
1. Adugbo wo ni ayeye isile naa ti waye? Ilu wo ni?
2. Ojo wo ni won si ile naa?
3. Asiko wo pato ni ayeye isile yii beere?
4. Iru ile wo ni won n si?
5. Ta ni o tile ko ile naa? Se okunrin ni tabi obinrin? Ise wo ni eni ti o ko ile na nse?
6. Aso wo ni Onile naa ati awon eniyan re wo?
7. Bawo ni irisi Onile se ri lojo naa?
8. Iru eto wo ni won se fun ayeye yii?
9. Nje alufaa tabi aafaa ile – ijosin onile naa wa gbadura nibe? Royin bi eto adura naa seri?
10. Se won ta okun si enu ona ile naa?
11. Tani oge okun yii?
12. Iru awon eeyan wo lo pese sibi ayeye isile naa? Daroku die lara awon eeyan Pataki to pese sibe
13. Nje won yan alaga nibi isele yii?
14. Royin ipa ti alaga naa ko
15. Nje won pagbo ijo fun ayeye isile yii?
16. Iru elere wo ni won pe sibe?
17. Nje ere won naa dun? Royin bi awon eeyan se ta elere yii lore to lasiko to n ki won
18. Nje akewi wa kewi nibe?
19. Bawo ni agbo ijo seri? Awon wo lo side ijo?
20. Se asemoju ni won se ere nibi ayeye isile yii?
21. Iru onje wo ni won pese fun awon to pese sibi ayeye isile naa?
22. Se gbogbo eyan to wa loju agbo ni won fun ni ounje ati nnkan mimu?
23. Iru eto wo ni Onile se fun oti? Iru oti wo lo si pese sibe?
24. Kini ipa ti awon ebi ore Onile ko?
25. Nje a ri awon ebi ebi ati ore onile nibe?
26. Nje awon ayaworan wa sibe?
27. Asiko wo ni ayeye isile naa pari?
IDANRAWO
Ko aroko atonisona oniroyin lori ijanba oko kan ti o se oju re
No comments:
Post a Comment