E ma je ka paro tiranwaje; gbogbo wa la feran ounje bii ikan inu okiti-ogan. Eyi lo fa a ti mo fe fi yannana ounje ti a n pe ni amala lafun.
Fun anfaani awon to setan ati gbo bi isu se ku ati bi obe se be e, e je ki a gunle esin idanilekoo.
Okan lara ounje nile Yoruba ni Amala. Ounje okele ti a maa n fi obe je ni. Bi o tile je wi pe obe bi ila, ewedu, ogbolo lo maa n ba amala se regi ju, sibe, ko fee si iru obe ti eniyan ko le fi je amala titi to fi de ori obe-iba.
Ege, isu tabi ogede ni awon Yoruba maa n lo lati fi se elubo ti o n di ounje ti won n pe ni amala. Elubo (iyefun) ti a fi ege_ iyen gbaguda, se ni a n pe ni elubo lafun. Nigba ti won ba wa ege loko, won yoo be e feerefe, won yoo si re e sinu omi fun ojo meloo kan, won yoo si gun un.
Leyin eyi won yoo sa a. Laigbe tan ni won yoo lo o ti yoo si kunna. Nigba ti won ba fe fi se amala, won yoo fi kanun die sinu omi re. Bi won ba n ro o yoo maa fa yoo ni.
Oro si po ninu iwe kobo, E je ka tesiwaju ninu ojulowo eko ede Yoruba naa.