Friday, January 25, 2019

Ami Ohun Ati Apeere



Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii:
(1) Ohun isale
(2) Ohun aarin
(3) Ohun oke

Bi a ba n ko ede Yoruba sile, a maa n lo awon ami ohun lati ya awon ohun Yoruba wonyii soto. Fun apeere:
Ohun isale = ami ohun \
Ohun aarin = ami ohun -
Ohun oke    = ami ohun /

Lopolopo igba, o maa n wulo fun akekoo lati lo awon ami ohun orin ti a ko sisale wonyii lati ranti awon ami ohun Yoruba.
Ohun isale = ami ohun \ = d (do)
Ohun aarin = ami ohun - = r (re)
Ohun oke.   = ami ohun / = m (mi)

Ami ohun isale: (i) konko (dododo) (ii) asa (dodo) (iii) ojo (dodo) (iv) akalamagbo (dododododo)
Ami ohun aarin: (i) aso (rere) (ii) eran (rere) (iii) sobolo (rerere)
Ami ohun oke: (i) ranti (mimi) (ii) boya (mimi) (iii) lagbaja (mimimi)
Nje O Ti Ka:

1. Foniimu Faweli Ede Yoruba


Ila Kiko Nile Yoruba (Yoruba Tribal Marks)



“Aluwala olonginin, ogbon ati keran je ni”; asa ila kiko ni gbolohun yii n fi ogbon bawi nitori pe ogboogbon ni ila kiko gba di asa nile kaaro-o-jiire.

Orisirisi itan agboso ni o ro mo asa yii. Itan kan toka si I pea won eru nikan ni won n ko ila nile Yoruba laye atijo (awon eru oba). Amo sababi kan mu ki won fi ibinu ko ila fun eru kan gege bi ijiya fun ese re laimo pe ila ti a ko fun eru yii yoo mu un tubo rewa si i ni. Nigba ti ila naa ti so eru ohun di arewa ni oba naa ba pinnu pe oun  naa yoo ko irufe ila bee. Nigba ti oloola bere si ni ko ila fun oba, tiroratirora ni debi pe oba ohun ko le mara duro ko ila naa tan. Iru iwa yii lo bi owe Yoruba to so pe “Tita riro laa kola, amo ti o ba jinna tan nii doge”. Itan yii fi han pe bi ila kiko se di ohun amusoge lawujo awon Oduduwa niyen.

A si tun ri itan miiran to fi han pe nigba laelae, nile Yoruba, ogun ati ikonileru gbile bi owara-ojo; eyi si n ko orisirisi ipinya airotele ba awon ebi (bi ogun ati ikonileru se n ya oko ati iyawo, bee ni o n ya awon obi kuro lodo awon omo won). Eyi lo mu ki awon ebi kookan gunle orisi ila kiko gege bi ogbon idanimo ntori igbagbo Yoruba wi pe lojo eni ti o ku ati eni to sonu yoo pade ara won.

Nje ki wa ni awon idi ti Yoruba fi n ko ila? (i) fun idanimo (ii) fun oge sise (iii) fun igbelaruge asa Yoruba.

Orisirisi ni ila kiko ni ile Yoruba. Bee ni o si yato si ara won lati agbegbe kan si ekeji. Awon ila bi pele, abaja, baamu, abaja pelu baamu, gonbo, gonbo pelu baamu, keke, ture, ati bee lo ni won n ko nile Yoruba sugbon eya Yooba kookan ni o ni orisi ila tire.

Si tun se Pataki fun wa lati ranti pe eniyan ti o yan ise ila kiko laayo ni a n pe ni Oloola. Iru ise bayii si le je ajogunba tabi kiko lati inu ebi to yan an laayo.
Nje O Ti Ka:

Iro Ohun ati Ami Ohun (Yoruba Tonal Sounds and Signs)


Ifa ati Eko Imo Ijinle Saikoloji


Itoju Ara Ati Ayika (Cleanliness)



Lati le dena arun ati aisan ni imototo fi se Pataki. Ona ti a si n gba ni imototo ni ki a se itoju ara ati ayika.
1.       Iwe wiwe wa lara ipa ti eniyan maa n ko lati toju ara. Ki a fi ose ati kan-in-kan-in ti o dara pelu girisi (ipara) fun ara ni ewa ti o ye.
2.       Eyin fifo se Pataki fun enikeni to ba few a ni imototo. Eyi se Pataki loorekoore nigba ti eniyan ba ji lowuro ati nigba ti eniyan ba fe lo sun. Burosi tabi pako irunyin ni a fi n foe yin mo.
3.       Itoju irun-ori ti wa lati igba laelae titi di oni; tokunrin tobinrin lo si maa n toju irun. Awon obinrin gbodo se irun ni kiko tabi ni didi nigba ti awon obinrin maa n ge irun won . O tun je kannpa lati maa fi omi ati ose fo irun wa.
4.       Itoju eekanna owo ati eekanna ese nipa ki a maa ge won, ki a si maa fo won lati dekun idoti to fe tabi to le farapamo sisun awon eekanna wa.
5.       Itoju aso o gbeyin ninu akitiyan lati dena arun to le kolu ara nipa ki eniyan ma wa ni imototo. Nse ni a gbodo maa fo awon aso wa pelu ose ati omi to mo.
6.       Itoju ayika (yala_ ile-igbe, ile-eko, ile-ise, tabi oja) se Pataki bakan naa. Eyi ni ko ni je ki eniyan je oye adara-lode-ma-dara-nile tabi adara-nile-ma-dara-lode. Lojoojumo ni o ye ki a maa fi igbale gba gbogbo ayika wa. A sit un gbodo maa gbon gbogbo panti ati jankariwo to so mo ile. A gbodo sa gbogbo agolo, igo-afoku, ewe ati ora tabi ohunkohun to le ko ijamba ba eniyan. A gbodo maa gba, ki a si tun maa fo oju gota ati oju-ona agbara, ki a si tun di awon ibi ti salanga ba ti fo lati dena arun ti eniyan le ko lati ipase oorun buruku. A gbodo maa se itoju ti o ye fun awon ile-iwe, ile-igbonse ati ati ayika idana. A gbodo maa ro awon oko ayika, ki a sit un ko gbogbo ohun ti ejo, efon, akeekee ati eku le farapamo si se eniyan ni ijamba jina si ayika ileegbe.
Ise imototo ko yo enikeni sile; ijoba, elegbejegbe,odo adugbo nitori pe agbajowo ni a fi n soya.
Nje O Ranti :

1. Orisirisi Oro-Ise 2

Sunday, December 23, 2018

Igbeyin Lalayo N Ta (Ori Kerin)

Ise Agbe Nise Ile Wa

Obisesan ati egbon re deyin leyin ise alakowe (a-n-so-tai-morun) leyin ti ori ti ko won yo lowo awon agbenipa ni ilu Ibadan.

Ni kete ti won pada de aba won ni won ti gbase alagbaro oko koko ni Ikoro ti o wa ni itosi Ijero.

Oruko oluko ti o ni oko koko n je Lakunle, eni ti o ni iyawo meta.

Ile ti su patapata ki Obisesan ati egbon re to de oko baba yii nitori pe won rin ibuso ti o gba won ni wakati meta.
Kaa Siwaju Sii >>>

Saturday, December 22, 2018

Ore Mi lati owo Aderibigbe Morohunmubo (iran 11-15)


(11) Iran Kokanla: Femi ati Sola se igbeyawo alarinrin won si se isinmi igbeyawo won ni Johanesibogi ni Guusu Orilede Afirika (Johannesburg, South Africa). O ra oko ayokele titun fun Sola nitori pe inu re dun gidigidi pe ni ale ojo igbeyawo, o ni o ja ibale Sola, iyawo re.

(12) Iran kejila: Sola ni oyun inu Femi si dun; eyi ati awon isele miiran ni iran kejila dale.

(13) Iran Ketala: Femi n se imurasile lati lo si London lati gba imo kun imo.

(14) Iran Kerinla: Sola so fun Kunbi nile won wi pe Femi yoo lo si London ati bee lo.

(15) Iran Karundinlogun: Iran yii so nipa bi Kunbi se lo si odo ore re ti n je Fikemi. Fikemi si mu un lo si odo babalawo leyin ti o pa iro fun un eniyan ti gba oko oun. Babalawo si fun Kunbi ni oogun ife ti yoo fi gba oko re pada.

Friday, December 21, 2018

Ore Mi lati owo Aderibigbe Morohunmubo (iran 6-10)


(6) Iran Kefa: Ni iran yii ni a ti ri Femi ati Sola ti won lo wo sinnima “Taxi Driver” ti Ade Love se. Ni gbara ti won kuro ni sinnima, won gba ile ounje lo nibi ti Femi ti so fun Sola pe oun feran lati fi se iyawo oun; oro won si wo.

(7) Iran Keje: Ni iran yii ni a ti fi han pe Femi kii se akuse (omo Oloye Odunwo nii se). Nigba ti Kunbi mo eyi, o bere si ni ke abamo wi pe kani oun ti mo ni oun o ba ti mu Femi lore. Lati igba yii ni o ti n da orisirisi ogbon lati fa oju Femi mora.

(8) Iran Kejo: Sola n se ipalemo fun sise agunbaniro. Eyi ati awon ohun miiran ni iran kejo dale.

(9) Iran Kesan-an: Awon obi Femi ati obi Sola mo ara won, won si tibe mu ojo igbeyawo.

(10) Iran Kewaa: Femi pa ni dandan fun Sola lati dekun sise ore pelu Kunbi nitori awon iwa agabangebe ti o kun owo re. Eyi ati awon isele miiran ni iran kewaa dale.

Thursday, December 20, 2018

Ore Mi lati owo Aribigbe Morohunmubo (iran 1-5)


(1) Iran Kin-in-ni: Sola ati Kunbi pade Femi nigba ti won n rin lo ninu ogba Yunifasi. Femi beere ona gbogan ere idaraya, Sola si mu un lo ibe awon mejeeji si ti ipase eyi di ore wolewode.

(2) Iran Keji: Ori ironu ni baba Sola (iyen Kola Egbeda) wa nigba ti iyawo re wole de, o si fi oko re lokan bale lori gbogbo ohun ti n dun un lokan. Kop e lale ojo naa ni Sola de lati ile-iwe lati wa beere fun owo ise asetilewa egberun marun-un naira (N5000). Ebe Egbeda je, won mu lale ojo naa, won si lo sun; Iya Sola si la ala buburu kan.

(3) Iran Keta: Kunbi lo sile, o ba baba re ti n gbafe ninu agbala nla ile won to rewa ringindin. O beere owo lowo baba re, baba re ko besu begba ti o fi fun un ni ohun ti o n fe bi o tile je pe ko kunle ki baba re nigba ti o wole gege bi o ti ye ki ojulowo omo Yoruba ti o gbekoo se ki agbalagba. Eyi lo mu ki Nura (omo-odo awon Kunbi) ati Asogba bere si ni sapejuwe Kunbi gege bi alailekoole, oninakuna, olojukokoro, ati oniwokuwo omo.

(4) Iran Kerin: Kunbi ati Sola, ore re, wa ninu yara won ninu ogba Yunifasiti. Kunbi n ba Sola ro ejo amo Sola n fi ogboogbon ka iwe re bi se n takuroso. Won soro kan Femi; Kunbi si n je ki o ye Sola pe oun ko gba ti Femi rara nitori pe olowo ni oun maa n ta si amo sibe, Sola feran Femi pupo.

(5) Iran Karun-un: Femi so nipa Sola fun awon obi re. Eyi mu ki inu awon obi Femi tubo dun sii nitori pe won ti n reti ki Femi pinnu lati fe omobinrin miiran leyin ti Titilayo (iyawo re akoko) ti ku. Awon obi Femi tubo ki Femi laya pe awon fowo sii. Eyi mu ki Femi pinnu lati da enu ife ko Sola ati wi pe oun yoo feran lati fi Sola se iyawo oun.

Ami Ohun Ati Apeere

Didun ohun se pataki pupo ninu ede Yoruba. Orisi ohun meta ni ede Yoruba ni. Awon ohun naa ni wonyii: (1) Ohun isale (2) Ohun aarin (3) Ohun...

Word of the Day

Quote of the Day

Article of the Day

This Day in History

Today's Birthday

Today's Holiday